Hymn 631 – MO ti seleri Jesu | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "MO ti seleri Jesu" (C&S Hymn #631, Yoruba). MO ti seleri Jesu, Lati sin Ọ dopin; Ma wa lọdọ mi titi, Baba mi, Ọrẹ mi;…

Hymn 631 – MO ti seleri Jesu | C&S Yoruba Hymnary
MO ti seleri Jesu, Lati sin Ọ dopin; Ma wa lọdọ mi titi, Baba mi, Ọrẹ mi; Emi ki y'o bẹru ogun, B'Iwọ ba sunmọ mi; Emi ki y'o si sina, B'O ba f'ọna han mi Jẹ ki n mọ p'O sunmọ mi, 'Tor' ibajẹ ayé; Ayé fẹ gba ọkan mi, Ayé fẹ tan mi jẹ; Ọta yi mi ka kiri, Lode ati ninu; Sugbọn Jesu, sunmọ mi, Dabobo ọkan mi, Jẹ ki emi k'o ma gbọ, Ohun Rẹ, Jesu mi, Ninu igbi ayé yi, Titi nigba gbogbo; Sọ, mu k'o da mi l'oju, K'ọkan mi ni'janu, Sọ, si mu mi gbọ Tirẹ, 'Wọ Olutọju mi. 'Wọ ti seleri, Jesu, F'awọn t'o tẹle Ọ; Pe ibikibi t'O wa, L'awọn yoo si wa; Mo ti seleri, Jesu, Lati sin Ọ dopin, Jẹ ki n ma tọ Ọ lẹhin, Baba mi, Ọrẹ mi. Jẹ ki n ma ri 'pasẹ Rẹ, Ki n le ma tẹle Ọ, Agbara Rẹ nikan ni, Ti mba le tẹle Ọ; Tọ mi, pe mi, si fa mi, Di mi mu de opin; Si gba mi si ọdọ Rẹ, Baba mi, Ọrẹ mi. AMIN

Hymn 631 – MO ti seleri Jesu | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia