Hymn 630 – KERUBU Serafu, e damure | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "KERUBU Serafu, e damure" (C&S Hymn #630, Yoruba). KÉRÚBÙ Séráfù, ẹ damure, Ẹ mura giri (3) Ẹyin eniyan mi. Ẹ gb' asia…
KÉRÚBÙ Séráfù, ẹ damure, Ẹ mura giri (3) Ẹyin eniyan mi. Ẹ gb' asia yin soke s'Ọba ogo, Ẹ mura giri (3) &c. Olubukun l'Ẹni t'o mbọ l'okọ Rẹ, Ẹ mura giri (3) &c. Ẹ lọ wo Mattiu ori kẹdọgbọn, Ẹ mura giri (3) &c. Ẹ mase bi wundia marun t'o s'aigbọn, Ẹ mura giri (3) &c. Sugbọn se bi wundia marun t'o l'ọgbọn Ẹ mura giri (3) &c. Ẹ f'ororo s'atupa yin, Séráfù, Ẹ mura giri (3) &c. Ẹ f'ororo s'atupa yin, Kérúbù Ẹ mura giri (3) &c. Emi L'ẸNISAJU at' ẸNIKẸHIN Ẹ mura giri (3) &c. Ẹyin ayanfẹ mi ti mo ti yan Ẹ mura giri (3) &c. Ẹ mase tun sunmọ ohun aimọ Ẹ mura giri (3) &c. W'ori kejileladọta Isaiah, Ẹ mura giri (3) &c. Ẹ du k'ẹ j'ẹni 'gbala nitotọ, Ẹ mura giri (3) &c. Ẹyin Olori ati ọmọ ẹsẹ Ẹ mura giri (3) &c. Jade lo wasu ihin-rere Mi, Ẹ mura giri (3) &c. Ẹ sọ f'awọn ọrẹ at'ara wa, Ẹ mura giri (3) &c. Ki wọn w'ọkọ igbala k'o to kun Ẹ mura giri (3) &c. Kérúbù Seraf' l'ọkọ 'gbala na, Ẹ mura giri (3) &c. Wo Mattiu karun ẹsẹ kẹtala Ẹ mura giri (3) &c. Ade Ogo y'o jẹ tiyin ni 'kẹhin, Ẹ mura giri (3) &c. Ẹ ma sọna pẹlu adura Ẹ mura giri (3) &c. Ẹ mura giri ẹyin eniyan mi, Ẹ mura giri (3) &c. Ẹ fi Ogo fun Baba wa l'oke Ẹ mura giri (3) &c. Ẹ f'Ogo f'ỌMỌ at' ẸMI MIMỌ Ẹ mura giri (3) &c. ẸMI ni O wa tit' ayé AINIPẸKUN. Ẹ mura giri (3) &c. AMIN
Hymn 630 – KERUBU Serafu, e damure | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia