Hymn 61 – BABA wa ti mbe l'orun | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "BABA wa ti mbe l'orun" (C&S Hymn #61, Yoruba). 1. BABA wa ti mbẹ l'ọrun, Ọwọ forukọ Rẹ, Ifẹ tirẹ ni ka se Bi wọn ti n…

Hymn 61 – BABA wa ti mbe l'orun | C&S Yoruba Hymnary
1. BABA wa ti mbẹ l'ọrun, Ọwọ forukọ Rẹ, Ifẹ tirẹ ni ka se Bi wọn ti n se lọrun, Fun wa l'Ounjẹ ojọ wa 'Dari ẹsẹ ji wa, Gba wa lọwọ idanwo, Gba wa lọwọ ewu. 2. Iwọ to gbọ t'Elijah L'ẹba odo Kedron Iwọ to gbọ ti Daniel, Ko gbọ ti wa loni, Fun wa niru agbara To fi f'awọn Apostle K'awa le wulo fun Ọ Ka jere bi ti wọn. 3. Fun wa lọkan igbagbọ Ti ki y'o yẹ lailai, Ka gbẹkẹle Ọ titi, A o fi r'oju Rẹ, Jẹ ka le ni ireti, Ninu Iwọ nikan, Ka nifẹ s'ẹnikeji, Ka si n'iwa pẹlẹ. 4. Baba a si tun mbẹ Ọ, Ani fun Olori wa, Ko fi Ẹmi meje Rẹ, Se 'tura f'ọkan rẹ, Jẹ ki awa le ma rin Lọna to n tọ wa si, Ko le ko wa de Canaan Niwaju Itẹ Rẹ. 5. Iwọ to gbọ ti Sedrak, Mesak, Abednego Gbọ t'awa Ẹgbẹ Seraf', Gba t'a ba n ke pe Ọ Fi agbara Rẹ wọ wa Bi ti wolii isaju Ka ni 'gboya bi tiwọn, Ka sẹgun ayé yi. 6. Awọn ọmọ Israel, Ninu rin ajo wọn, Iwọ lo n s'amọna wọn, Ati abo fun wọn Bi wọn ti n dẹsẹ si Ọ, Bẹẹ lo n dariji wọn, Jọwọ ko dariji wa, Awa Ẹgbẹ Séráfù. 7. Ọlọrun Abrahamu, Ọlọrun Isaaki, Ati Ọlọrun Jakọbu, Awa f'ọpẹ fun Ọ, Ogo, iyin, ọlanla S'Ẹni Mẹtalọkan, Halleluyah s'Ọlọrun, Ayé ainipẹkun AMIN

Hymn 61 – BABA wa ti mbe l'orun | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia