Hymn 060 – AWA egbe kerubu | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "AWA egbe kerubu" (C&S Hymn #060, Yoruba). 1. AWA ẹgbẹ Kérúbù, Ati Séráfù layé Awa mbẹbẹ fun 'ranwọ Agbara Ẹmi Mimọ A!…
1. AWA ẹgbẹ Kérúbù, Ati Séráfù layé Awa mbẹbẹ fun 'ranwọ Agbara Ẹmi Mimọ A! Baba sanu fun wa Ko dari ẹsẹ ji wa. 2. Ki fitila Rẹ ma ku Ninu Ijọ Séráfù Ki gbogbo isesi wa Fi wa han bi ọmọ Rẹ. A! Baba sanu fun wa Ko dari ẹsẹ ji wa. 3. Mase ta wa nu kuro Iwọ Olugbala wa K'awa ma ba sako lọ, Mu wa rin ọna tire. Egbe: A! Baba sanu fun wa Ko dari ẹsẹ ji wa. 4. Jehovah Jire Baba, Pese f'awọn alaini, At'awọn ti ko ri se, Ma sai ranti wọn loni. A! Baba sanu fun wa Ko dari ẹsẹ ji wa. 5. Ẹsẹ wa ti papọ ju, Bi yanrin eti okun, Awa n fẹ 'mularada, Iwẹnumo ẹsẹ wa. A! Baba sanu fun wa Ko dari ẹsẹ ji wa. 6. Jehovah Emmanueli Iwọ ni ireti wa, Mase jẹ koju tiwa L'ọjọ nla ọjọ 'dajọ. Egbe: A! Baba sanu fun wa Ko dari ẹsẹ ji wa. 7. Ọdaguntan Ọlọrun, Baba at'Ẹmi Mimọ, Wẹ wa mọ patapata, Ko to kuro layé yi. Egbe: A! Baba sanu fun wa Ko dari ẹsẹ ji wa. AMIN
Hymn 060 – AWA egbe kerubu | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia