Hymn 609 – OJO 'dajo ojo eru | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "OJO 'dajo ojo eru" (C&S Hymn #609, Yoruba). ỌJỌ 'dajọ ọjọ ẹru! Gbọ bi ipe ti n dun to! O ju ẹgbẹrun ara lọ, O si n mi…

Hymn 609 – OJO 'dajo ojo eru | C&S Yoruba Hymnary
ỌJỌ 'dajọ ọjọ ẹru! Gbọ bi ipe ti n dun to! O ju ẹgbẹrun ara lọ, O si n mi gbogbo ayé, Bi ẹsun na, Y'o ti damu ẹlẹsẹ. Wọ Onidajọ l'awa wa, T'o wọ ogo nla l'asọ; Gbogbo wọn ti n wo ọna Rẹ, 'Gbana ni wọn o ma yọ, Olugbala, Jẹwọ mi ni ọjọ na. Ni pipe Rẹ oku o ji, Lat'okun, ile s'iye: Gbogbo ipa ayé y'o mi, Wọn o salọ loju RẸ; Alaironu, Yoo ha ti ri fun ọ? Esu ti n tan ọ nisinyi, Iwọ mase gbọ tirẹ, 'Gbati ayé yi ba kọja; Y'o ri ọ ninu ina; Iwọ ronu, Ipo rẹ ninu ina. Labẹ ipọnju at'ẹgan, K'eyi gba ọ n'iyanju; Ọjọ Ọlọrun mbọ tete, 'Gbana ẹkun y'o d'ayọ, A o sẹgun, 'Gbati ayé ba gbina. AMIN

Hymn 609 – OJO 'dajo ojo eru | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia