Hymn 608 – NIGBAT' idanwo yi mi ka | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "NIGBAT' idanwo yi mi ka" (C&S Hymn #608, Yoruba). NIGBAT' idanwo yi mi ka, Ti idamu ayé mu mi; T'ọta fara han bi ọre,…

Hymn 608 – NIGBAT' idanwo yi mi ka | C&S Yoruba Hymnary
NIGBAT' idanwo yi mi ka, Ti idamu ayé mu mi; T'ọta fara han bi ọre, Lati wa iparun fun mi, Oluwa, jọ ma sai pe mi, B'o ti pe Adam nin' ọgba, Pe' ―Nibo l'o wa ẹlẹsẹ?‖ Ki n le bọ ninu ẹbi na. Nigba t'Esu n'nu 'tanjẹ rẹ, Gbe mi gori oke ayé; T'o ni ki n tẹriba fun oun, K'ohun ayé le jẹ temi. Oluwa, jọ ma sai pe mi, B'o ti pe Adam nin' ọgba, Pe' ―Nibo l'o wa ẹlẹsẹ?‖ Ki n le bọ ninu ẹbi na. Nigba t'ogo ayé ba fẹ fi, Tulasi mu mi rufin Rẹ; To duro gangan lẹhin mi, Ni ileri pe ―Ko si nkan‖ Oluwa, jọ ma sai pe mi, B'o ti pe Adam nin' ọgba, Pe' ―Nibo l'o wa ẹlẹsẹ?‖ Ki n le bọ ninu ẹbi na. Nigba ti igbẹkẹle mi, Di t'ogun ati t'orisa; T'ogede di adura mi, Ti ọfọ di ajisa mi. Oluwa, jọ ma sai pe mi, B'o ti pe Adam nin' ọgba, Pe' ―Nibo l'o wa ẹlẹsẹ?‖ Ki n le bọ ninu ẹbi na. Nigba ti mo fẹ lati rin, L'adamọ at'ifẹ n'nu mi; T'ọkan mi n se hila-hilo, Ti n ko gbona, ti n ko tutu. Oluwa, jọ ma sai pe mi, B'o ti pe Adam nin' ọgba, Pe' ―Nibo l'o wa ẹlẹsẹ?‖ Ki n le bọ ninu ẹbi na. Nigba mo sọnu bi aja, Laigbọ ifere ọdẹ mọ; Ti n ko nireti ipada, Ti mo n pafọ ninu ẹsẹ Oluwa, jọ ma sai pe mi, B'o ti pe Adam nin' ọgba, Pe' ―Nibo l'o wa ẹlẹsẹ?‖ Ki n le bọ ninu ẹbi na. Nigba ti ko s'alabaro, Ti olutunu si jina, T'ibanujẹ b'iji lile, Tẹ ori mi ba n'ironu Oluwa, jọ ma sai pe mi, B'o ti pe Adam nin' ọgba, Pe' ―Nibo l'o wa ẹlẹsẹ?‖ Ki n le bọ ninu ẹbi na. AMIN Oluwa, jọ ma sai pe mi, B'o ti pe Adam nin' ọgba, Pe' ―Nibo l'o wa ẹlẹsẹ?‖ Ki n le bọ ninu ẹbi na.

Hymn 608 – NIGBAT' idanwo yi mi ka | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia