Hymn 592 – WA, ma sise | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "WA, ma sise" (C&S Hymn #592, Yoruba). WA, ma sisẹ, Tani gbọdọ sọlẹ ninu oko, 'Gbati gbogbo eniyan n kore jọ? 'Kaluku…
WA, ma sisẹ, Tani gbọdọ sọlẹ ninu oko, 'Gbati gbogbo eniyan n kore jọ? 'Kaluku ni Baba pasẹ fun pe Sisẹ loni. Wa, ma sisẹ, 'Gba 'pe giga ti angẹli ko ni Mu 'hinrere tọ t'agba t'ewe lọ; di Ra 'gba pada, wawa l'akoko n lọ, Ilẹ su tan. Wa, ma sisẹ, Oko pọ, alagbase ko si to, A n'ibi titun gba, a ni 'po 'ro; Ohun ọna jijin, at' itosi, N kigbe pe, Wa. Wa, ma sisẹ, Le 'yemeji oun aigbagbọ jina, Ko s'alailera ti ko le se nkan; di Ailera l'Ọlọrun a ma lo ju Fun 'sẹ nla Rẹ. Wa, ma sisẹ, 'Sinmi ko si, nigba t'ise ọsan, Titi orun yoo fi wọ l'alẹ, Ti awa o si gbọ ohun ni pe O seun, ọmọ. Wa, ma sisẹ, Lala ni dun, ere rẹ si daju, 'Bukun f'awọn t'o f'ori ti d'opin; Ayọ wọn, 'sinmi wọn, y'o ti pọ to, Lọd' Oluwa! AMIN