Hymn 591 – TAN 'mole Re si wa | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "TAN 'mole Re si wa" (C&S Hymn #591, Yoruba). TAN 'mọlẹ Rẹ si wa, Loni yi Oluwa; Fi ara Rẹ han wa, N'nu ọrọ Mimọ Rẹ; Jọ…

Hymn 591 – TAN 'mole Re si wa | C&S Yoruba Hymnary
TAN 'mọlẹ Rẹ si wa, Loni yi Oluwa; Fi ara Rẹ han wa, N'nu ọrọ Mimọ Rẹ; Jọ m'ọkan wa gbona, K'a ma wo oju Rẹ, K'awọn 'mọde le kọ Iyanu ọrẹ Rẹ. Mi si wa Oluwa, Ina Ẹmi Mimọ , K'a le fi ọkan kan, Gbe orukọ Rẹ ga; Jọ fi eti igbọ, At'ọkan ironu, Fun awọn ti a n kọ, L'ohun nla t'O ti se. Ba ni sọ, Oluwa, Ohun to yẹ k'a sọ, Gẹgẹ bi ọrọ Rẹ, Ni ki ẹkọ wa jẹ; K'awọn aguntan Rẹ, Le ma mọ ohun rẹ, Ibi t'O n tọ wọn si, Ki wọn si le ma yọ. Gbe 'nu wa, Oluwa, K'ifẹ Rẹ jẹ tiwa, Iwọ nikan la o fi Ipa wa gbogbo sin; K'iwa wa jẹ ẹkọ, Fun awọn ọmọ RẸ, K'o si ma kede Rẹ, Ninu gbogbo ọkan. AMIN

Hymn 591 – TAN 'mole Re si wa | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia