Hymn 577 – OMO Olorun n lo s'ogun | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "OMO Olorun n lo s'ogun" (C&S Hymn #577, Yoruba). ỌMỌ Ọlọrun n lọ s'ogun, Lati gbade Ọba: Ọpagun Rẹ si n fẹ lelẹ, Ta…

Hymn 577 – OMO Olorun n lo s'ogun | C&S Yoruba Hymnary
ỌMỌ Ọlọrun n lọ s'ogun, Lati gbade Ọba: Ọpagun Rẹ si n fẹ lelẹ, Ta l'o s'ọm'ogun Rẹ. Ẹni ti o le mu ago na, T'o le bori 'rora, T'o le gbe agbelebu Rẹ, Oun ni Ọm' ogun Rẹ. Martyr ikini ti o kọ 'ku, T'o r'ọrun si silẹ; T'o ri Oluwa rẹ loke, T'o pe, k'o gba oun la. T'oun ti 'dariji l'ẹnu, Ninu 'rora iku, O bẹbẹ f'awọn t'o n pa lọ; Tani le se bi rẹ? Ẹgbẹ mimọ; awọn wọnni, T'Ẹmi Mimọ ba le; Awọn akọni mejila, Ti ko ka iku si. Wọn f'aya ran ida ọta, Wọn ba ẹranko ja; Wọn f'ọrun wọn lelẹ fun 'ku Tani le se bi wọn? Ẹgbẹ ogun, t'agba, t'ewe, T'ọkunrin, t'obinrin; Wọn y'itẹ Olugbala ka, Wọn wọ asọ funfun. Wọn de oke ọrun giga, di N'nu 'sẹ at'ipọnju, p Ọlọrun, fun wa l'agbara, K'a le se bi wọn. AMIN

Hymn 577 – OMO Olorun n lo s'ogun | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia