Hymn 576 – OM'-OGUN Krist, dide | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "OM'-OGUN Krist, dide" (C&S Hymn #576, Yoruba). ỌM'-OGUN Krist, dide, Mu hamọran yin wọ: Mu 'pa t'Ọlọrun fi fun yin…

Hymn 576 – OM'-OGUN Krist, dide | C&S Yoruba Hymnary
ỌM'-OGUN Krist, dide, Mu hamọran yin wọ: Mu 'pa t'Ọlọrun fi fun yin Nipa ti ọmọ Rẹ. Gbe pa Ọlọrun wọ, T'Oluwa ọm'-ogun, Ẹni t'o gbẹkẹle Jesu, O ju asẹgun lọ. Ninu ipa Rẹ nla, Oun ni ki ẹ duro, Tori k'ẹ ba le jija na, Ẹ di hamọra yin. Lo lat'ipa de'pa, Ma ja, ma gbadura; Tẹ agbara okunkun ba, Ẹ ja, k'ẹ si sẹgun. Lẹhin ohun gbogbo, Lẹhin gbogbo ija, K'ẹ le sẹgun n'ipa Kristi, K'ẹ si duro sinsin. AMIN

Hymn 576 – OM'-OGUN Krist, dide | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia