Hymn 558 – A DUPE lowo Oluwa | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "A DUPE lowo Oluwa" (C&S Hymn #558, Yoruba). A DUPẸ lọwọ Oluwa, Ẹ ki mi ku ewu, Fun irin ajo mi yi na; Ọpẹ fun Oluwa.…
A DUPẸ lọwọ Oluwa, Ẹ ki mi ku ewu, Fun irin ajo mi yi na; Ọpẹ fun Oluwa. Kérúbù pẹlu Séráfù; F'Ogo f'orukọ Rẹ, F'ẹni to d'Ẹgbẹ yi silẹ, Oun ni Ọba Ogo. Ẹ ho, ẹ yọ, kọrin ogo, Jesu Ọba Ogo; Orukọ Rẹ kari ayé, O mu mi lọ, mo bọ. Ọpẹ lo yẹ Ọ, Oluwa, F'abo Rẹ l'ori mi, Yika orilẹ ede gbogbo, Ogo f'orukọ Rẹ. K'okiki Rẹ yika ayé, Ma bọ, Oluwa mi, Ọba Mimọ, Ọba aiku, Ẹni Mẹtalọkan. Ẹ kọrin Ologo Mimọ, Ọpẹ ni f'Oluwa, A lọ, a bọ, l'alafia, Mo dupẹ f'Oluwa. Ẹ ke Halle, Halleluyah, F'Ọlọrun Kérúbù; Ẹ ke Halle, Halleluyah, S'Ọlọrun Séráfù. AMIN
Hymn 558 – A DUPE lowo Oluwa | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia