Hymn 557 – Awa n'imole aye | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "Awa n'imole aye" (C&S Hymn #557, Yoruba). Awa n'imọlẹ ayé, Kérúbù Séráfù, Ilu ti a tẹ si oke, Bawo ni yo ti se…

Hymn 557 – Awa n'imole aye | C&S Yoruba Hymnary
Awa n'imọlẹ ayé, Kérúbù Séráfù, Ilu ti a tẹ si oke, Bawo ni yo ti se farasin, Jẹ k'a sisẹ- Jẹ k'a sisẹ, Jẹ k'a sisẹ- k'a le ri igbala n' ikẹhin. Tẹ 'ti lelẹ lati gbọ, Ọrọ ifẹ Jesu, Ti o n ke rara wi pé, Ha! ọmọ 'wo ha fẹran mi bi? Jẹ k'a sisẹ- Jẹ k'a sisẹ, Jẹ k'a sisẹ- k'a le ri igbala n' ikẹhin. Kérúbù oun Séráfù, Lọ si gbogbo agbayé, Mu ayé gbọ ọrọ mi, Ẹni ba gbọ y'o ri igbala, Jẹ k'a sisẹ- Jẹ k'a sisẹ, Jẹ k'a sisẹ- k'a le ri igbala n' ikẹhin. Ẹyin ara ati ọrẹ, Ẹ wa w'ọkọ 'gbala yi Ti Ọlọrun gbe kalẹ, Ara w'ọkọ k' ilẹkun to se. Jẹ k'a sisẹ- Jẹ k'a sisẹ, Jẹ k'a sisẹ- k'a le ri igbala n' ikẹhin. Ẹ ranti ọjọ Nọa, Ti ẹda n se dunia, Ti ẹranko fi w'ọkọ, Abamọ kọ ha fun wọn nikẹhin. Jẹ k'a sisẹ- Jẹ k'a sisẹ, Jẹ k'a sisẹ- k'a le ri igbala n' ikẹhin. Ohun ayé mb' ayé lọ, Ẹ lọ ranti aya Lot, Sugbọn t'igbala lo ju, Ki a mase k'abamọ nikẹhin. Jẹ k'a sisẹ- Jẹ k'a sisẹ, Jẹ k'a sisẹ- k'a le ri igbala n' ikẹhin. Baba jọ ran wa lọwọ, K'a le sisẹ Rẹ d'opin, Ki a gbọ ohun na pe, Kérúbù, Séráfù, gb' ere Rẹ, Jẹ k'a sisẹ- Jẹ k'a sisẹ, Jẹ k'a sisẹ- k'a le ri igbala n' ikẹhin. AMIN Jẹ k'a sisẹ- Jẹ k'a sisẹ, Jẹ k'a sisẹ- k'a le ri igbala n' ikẹhin.

Hymn 557 – Awa n'imole aye | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia