Hymn 550 – EYIN ara ati ojulumo | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "EYIN ara ati ojulumo" (C&S Hymn #550, Yoruba). ẸYIN ara ati ojulumọ, Ẹ wa wọle ki 'le ayọ to kun, Gbogbo ayé ni Jesu n…
ẸYIN ara ati ojulumọ, Ẹ wa wọle ki 'le ayọ to kun, Gbogbo ayé ni Jesu n pe tantan; Wa wọ ọkọ igbala yi ki o to kun. Yara wa, wa wọle, ) Jesu lo n pe yin tantan ) 3ce Ki ọkọ Noah ikẹyin yi ko to kun tan. Gbogbo Ẹgbẹ at' Ijọ Ọlọrun, Keferi ati Imale ilu; Gbogbo ayé ni Jesu n pe tantan, Wa wọ ọkọ igbala yi ki o to kun. Yara wa, wa wọle, ) Jesu lo n pe yin tantan ) 3ce Ki ọkọ Noah ikẹyin yi ko to kun tan. Ijọ Afrikan wa ba wa jọsin; Ati gbogbo Ijọ ọmọ 'bilẹ, Jesu Krist' lo wi pé ki e wa, Wa wọ ọkọ igbala yi ki o to kun. Yara wa, wa wọle, ) Jesu lo n pe yin tantan ) 3ce Ki ọkọ Noah ikẹyin yi ko to kun tan. Ọlọrun Shedrack lo n pe yin tantan, Ọlọrun Mesak lo n pe yin tantan, Ọlọrun Abednego lo n pe yin Wa wo ọkọ igbala yi ki o to kun Yara wa, wa wọle, ) Jesu lo n pe yin tantan ) 3ce Ki ọkọ Noah ikẹyin yi ko to kun tan. Ọlọrun Abram lo n pe yin tantan, Ọlọrun Isaac lo n pe yin tantan; Ọlọrun Jacob lo n pe yin tantan; Wa wo ọkọ igbala yi ki o to kun. Yara wa, wa wọle, ) Jesu lo n pe yin tantan ) 3ce Ki ọkọ Noah ikẹyin yi ko to kun tan. Ọlọrun Dafidi lo n pe yin tantan, Ọlọrun Daniel lo n pe yin tantan, Ọlọrun Batimeu lo n pe yin tantan, Wa wọ ọkọ igbala yi ki o to kun. Yara wa, wa wọle, ) Jesu lo n pe yin tantan ) 3ce Ki ọkọ Noah ikẹyin yi ko to kun tan. Ọlọrun Mary lo n pe yin tantan, Ọlọrun Martha lo n pe yin tantan, Ọlọrun Esther lo n pe yin tantan, Wa wọ ọkọ igbala yi ki o to kun. Yara wa, wa wọle, ) Jesu lo n pe yin tantan ) 3ce Ki ọkọ Noah ikẹyin yi ko to kun tan. Kérúbù ati Séráfù lo n pe yin, Ẹni Mimọ, Israeli lo n pe yin, Gbogbo Ogun Ọrun lo ni k'ẹ wa, Wa wọ ọkọ igbala yi ki o to kun. Yara wa, wa wọle, ) Jesu lo n pe yin tantan ) 3ce Ki ọkọ Noah ikẹyin yi ko to kun tan. AMIN Yara wa, wa wọle, ) Jesu lo n pe yin tantan ) 3ce Ki ọkọ Noah ikẹyin yi ko to kun tan.
Hymn 550 – EYIN ara ati ojulumo | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia