Hymn 549 – ODO Aguntan Olorun | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "ODO Aguntan Olorun" (C&S Hymn #549, Yoruba). ỌDỌ-Àgùntàn Ọlọrun, Jọ wẹ mi ninu ẹjẹ Rẹ; Sa jẹ ki n mọ 'fẹ Rẹ, gbana,…

Hymn 549 – ODO Aguntan Olorun | C&S Yoruba Hymnary
ỌDỌ-Àgùntàn Ọlọrun, Jọ wẹ mi ninu ẹjẹ Rẹ; Sa jẹ ki n mọ 'fẹ Rẹ, gbana, Irora dun, iku lere. f Fa ọkan mi kuro l'ayé, K'o jẹ k'o se Tirẹ titi, Fi edidi Rẹ s'aya mi, Edid' ifẹ titi aye. A! awọn wọnni ti yọ to, T'o f'iha Rẹ se 'sadi wọn, Wọn fi Ọ se agbara wọn, Wọn n jẹ, wọn si n mu ninu Rẹ. O kun wa loju p'Ọlọrun Fẹ m'awa yi lọ sin' ogo; Pe, O sọ ẹru dọm' Ọba, Lati ma jẹ faji lailai. Baba, mu wa ronu jinlẹ, K'a le mọ isẹ nlanla Rẹ, Ma sai tu okun ahọn wa; K'a le sọ ibu ifẹ Rẹ. Jesu, Iwọ l'Olori wa, 'Wọ la o tẹri wa ba fun, 'Wọ l'a o fi ọkan wa fun, B'a ku, b'a wa, k'a jẹ Tirẹ. AMIN

Hymn 549 – ODO Aguntan Olorun | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia