Hymn 055 – OLORUN Eleda jowo sunmo wa | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "OLORUN Eleda jowo sunmo wa" (C&S Hymn #055, Yoruba). 1. ỌLỌRUN Ẹlẹda / jọwọ sunmọ wa, Awa ọmọ Re de / lati juba Rẹ,…

Hymn 055 – OLORUN Eleda jowo sunmo wa | C&S Yoruba Hymnary
1. ỌLỌRUN Ẹlẹda / jọwọ sunmọ wa, Awa ọmọ Re de / lati juba Rẹ, Ran Séráfù t'ọrun / ati Kérúbù; Lati wa ba wa pe / lati jọ yin Ọ. 2. Baba Olubukun / bukun wa loni, Jẹ k'ipade oni / le mu eso wa, Jẹ ki ọmọ 'mọle / to wa l'okunkun, Wa sinu imọlẹ / lati ri'gbala. 3. Tikala Rẹ wasu / fun aguntan Rẹ, Majẹ ki wọn segbe, pe won sọdọ Rẹ, Majẹ k'ina Rẹ ku / n'ilẹ Yoruba, Jẹ ki ina Rẹ ma / tan nibẹ titi. 4. Awọn ti 'Wọ ti pe / ni ilu Eko, Ati gbogbo ayé / ma fi wọn silẹ, Ọkọ 'gbala kẹhin / to tun gbe kalẹ, Majẹ k'ẹranko wọ / l'akoko ti wa. 5. Ẹyin Ijọ Seraf' / ati Kérúbù, Ẹ ma jẹ ko rẹ yin, ẹ mase sọlẹ, Gbe 'da 'sẹgun soke, Jesu ti sẹgun; Nipa agbara Rẹ / awa yoo sẹgun. 6. Sugbọn k'a sotitọ / ni ilana Rẹ, Yoo si gbe wa nija, yoo duro ti wa, K'a fara da iya, ka tẹ siwaju, Oun to gbọ t'Abraham / yoo si gbọ tiwa. 7. Jesu Olugbala / Ọrẹ Ẹlẹsẹ, Jẹ ka se ifẹ Rẹ / ka tẹ s'ọna Rẹ, Jẹ ka fi iwa wa / p'ẹlomiran wa, Ko si fun wa n'ifẹ / larin ara wa. 8. A mbe Ọ, Ẹlẹda, Ọlọrun tiwa, Fun awọn ariran / ninu Ẹgbẹ yi, F'iran didan han wọn, si tun yan kun wọn, Mase jẹ ki esu / f'iran rẹ han wọn. 9. Nigba t'o ba si di / ọjọ ikehin, T'oju gbogbo ayé, yoo pe sọdọ Rẹ, Majẹ k'oju ti wa, ma jẹ ka sọkun, Jẹ k'awa Séráfù / ke Halleluya. AMIN

Hymn 055 – OLORUN Eleda jowo sunmo wa | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia