Hymn 541 – JESU, mo gb' agbelebu mi | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "JESU, mo gb' agbelebu mi" (C&S Hymn #541, Yoruba). JESU, mo gb' agbelebu mi, Ki n le ma tọ Ọ lẹhin, Otosi at' ẹni…

Hymn 541 – JESU, mo gb' agbelebu mi | C&S Yoruba Hymnary
JESU, mo gb' agbelebu mi, Ki n le ma tọ Ọ lẹhin, Otosi at' ẹni ẹgan, 'Wọ l'ohun gbogbo fun mi; Ti ini mi gbogbo segbe, Ti ero mi gbogbo pin; Sibẹ ọlọrọ ni mo jẹ! Temi ni Krist' at' Ọrun. Ẹda le ma wahala mi, Y'o mu mi sunmọ Ọ ni: Idanwo ayé le ba mi, Ọrun o mu 'sinmi wa; Ibanujẹ ko le se nkan, B' ifẹ Rẹ ba wa fun mi; Ayọ ko si le dun mọ mi, B' Iwọ ko si ninu rẹ. Ọkan mi gba igbala rẹ, Bori ẹsẹ at' esu, F'ayọ a wa ni ipokipo, Ma sisẹ, si ma jiya; Ro t' Ẹmi t'o wa ninu rẹ? At' ifẹ Baba si Ọ; 'W' Olugbala t'o ku fun ọ, Ọmọ ọrun, mase kun! Njẹ kọja lat' ore s'ogo, N'n' adura oun igbagbọ; Ọjọ ailopin wa fun Ọ, Baba y'o mu o de 'bẹ. Isẹ rẹ l' ayé fẹrẹ pin, Ọjọ ajọ rẹ mbuse, Ireti y'o pada s' ayọ, Adura s' orin iyin. AMIN

Hymn 541 – JESU, mo gb' agbelebu mi | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia