Hymn 540 – EWA 'tanna ooro kutu | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "EWA 'tanna ooro kutu" (C&S Hymn #540, Yoruba). ẸWA 'tanna oorọ kutu, 'Mọlẹ ọsan gangan, Pipọn orun ni ọjọrọ, di Wọn ti…
ẸWA 'tanna oorọ kutu, 'Mọlẹ ọsan gangan, Pipọn orun ni ọjọrọ, di Wọn ti n yara sa to! A n fẹ ẹnubode ọrun, Ita wura didan: Awa n fẹ Orun Ododo, Ti ki wọ titi lai. B' ireti giga wa layé, Ti n tete saki to! Abawọn melomelo ni, Nb'agbada Kristian jẹ? A n fẹ ọkan ti ki dẹsẹ; Ọkan ti a wẹ mọ; Ohun lati yin Ọba wa, Lọsan-loru titi. Nihin 'gbagbọ oun 'reti mbẹ, Lati tọ wa soke; Lohun, pipe alafia, Ju b'a ti le fẹ lọ: Nipa ifẹ oun 'rora Rẹ, Nitori iku Rẹ, Ma jẹ ka subu lọna Rẹ. K'a sọ ade wa nu. AMIN
Hymn 540 – EWA 'tanna ooro kutu | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia