Hymn 053 – KA wole f'Oba Ologo | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "KA wole f'Oba Ologo" (C&S Hymn #053, Yoruba). 1. 'K'A wolẹ f'Ọba Ologo Ẹni t'O n gbe 'nu imọlẹ, T'oju ẹlẹsẹ kan ko ri…

Hymn 053 – KA wole f'Oba Ologo | C&S Yoruba Hymnary
1. 'K'A wolẹ f'Ọba Ologo Ẹni t'O n gbe 'nu imọlẹ, T'oju ẹlẹsẹ kan ko ri Dariji, dariji. 2. Gbogbo Ọmọ Ẹgbẹ Séráfù, L'ọkunrin at'obinrin, K'a ronu ẹsẹ ti a da, K'a tọrọ 'dariji. 3. B'a ba mọ'ra wa l'ẹlẹsẹ, K'a jẹwọ rẹ lajẹtan, K'a ronu k'a si pawada, Baba yo dariji. 4. Ẹsẹ aini 'fẹ l'o pọju, Larin wa ba ti kunlẹ, Esu l'o n gb'ogun rẹ ti wa, Baba jọ dariji. 5. Ninu 'wa wa ati'se wa, Ninu ọrọ ẹnu wa, 'Nu gigan ẹnikeji wa, Dariji, dariji. 6. Gbogbo wa lati f'oju ri, 'Wo lo ran 'mọlẹ si wa, Lati fi ọna Rẹ han wa, Dariji, dariji. 7. Bi ko ba se anu Rẹ ni, Ka to de 'nu 'mọlẹ yi, Esu ba l'ayọ lori wa, Dariji, dariji. 8. Bi ko ba s'esu t'o n gb'ogun, A le fi ‘bi s'oloore, Jọwọ pa isẹ esu run, Dariji, dariji 9. Wo ti'ya ti Jesu wa jẹ, 'Ranti ogun ẹjẹ Rẹ, Nin'ọgba Getsemani. Dariji, dariji. 10. A dupẹ p'O ti gbọ tiwa, Ma jẹ k'a tun d'ẹsẹ mọ, Tun wa yipada Oluwa, Ka l'ayọ l'ọjọ kẹyin. AMIN

Hymn 053 – KA wole f'Oba Ologo | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia