Hymn 052 – BABA MIMO jowo gbo'gbe omo Re | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "BABA MIMO jowo gbo'gbe omo Re" (C&S Hymn #052, Yoruba). 1. BABA MIMỌ jọwọ gbọ'gbe ọmọ Rẹ MẸTALỌKAN MIMỌ ỌBA OGO Ẹgbẹ…
1. BABA MIMỌ jọwọ gbọ'gbe ọmọ Rẹ MẸTALỌKAN MIMỌ ỌBA OGO Ẹgbẹ aladura ipe na n dun, Ẹgbẹ Séráfù t'ayé ẹ mura. Wa ọrẹ mi, wa ka jumọ rin, F'oju ọkan wo agbala ni Nib'OLUDANDE wa n wi pé, BABA MIMỌ dariji. 2. Ogoji ọdun ni BABA fi gb'ẹbẹ, Ka le gb'ẹgbẹ to logo yi dide, Ogoji ọdun ni ỌMỌ fi bẹbẹ Lati d'ẹgbẹ Séráfù yi silẹ. 3. BABA OLUPESE jọ pese fun wa, OLUGBỌGBE ẸDA gbogb'ẹdun wa, OLUBUKUN-JULỌ lẹni ransẹ naa, MẸTALỌKAN ransẹ rere si wa. 4. f Ẹgbẹ akọrin ẹ tun ohun yin se, Ke Halleluya s'Ọba Olore Ẹgbẹ Aladura ẹ t'esu mọlẹ, K'ẸMI MIMỌ s'amọna Ẹgbẹ wa, 5. Ẹyin ariran nin'ẹgbẹ Séráfù, Mase boju w'ẹyin esu wa nibẹ, Mura giri k'esu ma fa ọ sẹhin, J'ẹni kikun laibẹru eniyan. 6. Awa dupẹ lọwọ rẹ ỌBANGIDI, ỌLỌRUN ALANU buk'ẹgbẹ wa, JEHOVAH SABAOTH jọwọ sunmọ wa, Sẹgun gbogb' ọta 'le ati t'ode. 7. f Ọpẹ lo yẹ ọmọ ẹgbẹ Kérúbù, Fun anu rẹ lori gbogb'ẹgbẹ wa Ẹlomiran jade nile o d'oku, A dupẹ fun abo to fi mbo wa. 8. p F'OGO fun BABA MIMỌ loke ọrun, Ẹ tun f'ogo fun ỌMỌ RẸ pẹlu, Ẹ f'ogo fun ẸMI to n dari wa MẸTALỌKAN MIMỌ lọpẹ yẹ fun. Wa ọrẹ mi, wa ka jumọ rin, F'oju ọkan wo agbala ni Nib'OLUDANDE wa n wi pé, BABA MIMỌ dariji. AMIN
Hymn 052 – BABA MIMO jowo gbo'gbe omo Re | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia