Hymn 501 – OLORUN WA, awa mbe O | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "OLORUN WA, awa mbe O" (C&S Hymn #501, Yoruba). ỌLỌRUN WA, awa mbẹ Ọ, Sọkalẹ si arin wa, Ran agbara 'sẹgun nla Rẹ,…
ỌLỌRUN WA, awa mbẹ Ọ, Sọkalẹ si arin wa, Ran agbara 'sẹgun nla Rẹ, S'ori awọn ọmọ Rẹ; F'ore ọfẹ igbala, Yi awa ọmọ Rẹ ka, K'a le ma yọ n'nu ore Rẹ, K'a si le sẹgun ọta. O d'ofo (4) Ajahula Sakula, Agbara ajẹ d'ofo. Ẹyin Angeli Olusẹgun, Sọkalẹ l'agbara Rẹ; Ẹ dide pẹl' ohun ija yin, Lati sẹgun f'Ijọ yi; Ẹmi-Mimọ'daba ọrun, Fi ore isẹgun Rẹ; Yi awa ọmọ Rẹ ka, K'a le ma yọ 'nu 'sẹgun. O d'ofo (4) Ajahula Sakula, Agbara ajẹ d'ofo. Kérúbù onida ina, Sọkalẹ l'agbara Rẹ; Maikel olori ogun wa, Sọkalẹ l'agbara Rẹ Awa ọmọ Rẹ duro; De agbara ina na, T'o sọkalẹ sara 'wọn, T'o sọtẹ s'awọn ọmọ Rẹ. O d'ofo (4) Ajahula Sakula, Agbara ajẹ d'ofo. Ọlọrun Alagbara nla, T'o pa ara Egypt run; T'o ri wọn sinu okun pupa, Ti wọn ko le dide mọ, Sọkalẹ Ẹlẹda wa, Doju ọta wa bo'lẹ, Ki wọn subu n'iwaju Rẹ, Ki wọn sidi 'tẹmọlẹ. O d'ofo (4) Ajahula Sakula, Agbara ajẹ d'ofo. Ẹ ma yọ ẹyin eniyan mi, Ninu agbara nla mi, Ẹ ho iho isẹgun nla, Bi t'awọn ọmọ Israel, Maikel ti sẹgun fun yin, O si di yin l'amure, Tẹ siwaju nipa agbara Rẹ, Ẹ ja k'ẹ si le sẹgun. O d'ofo (4) Ajahula Sakula, Agbara ajẹ d'ofo. Emi ni El El-Sahula, Ọba Ajasẹgun ni mi, Emi ni Jehofa Hullam, Ọba Awimayẹhun, Ẹ ma yọ ninu ore mi, K'ẹ si ma dupẹ pẹlu: Emi ni Asaholah, Ọba a-fi-di-p'ọ-tẹ-mọlẹ. O d'ofo (4) Ajahula Sakula, Agbara ajẹ d'ofo. AMIN O d'ofo (4) Ajahula Sakula, Agbara ajẹ d'ofo.
Hymn 501 – OLORUN WA, awa mbe O | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia