Hymn 500 – AWA l'Ẹgbẹ Kerubu Serafu | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "AWA l'Ẹgbẹ Kerubu Serafu" (C&S Hymn #500, Yoruba). AWA l'Ẹgbẹ Kérúbù Séráfù, T'Oluwa fun 'ra rẹ gbe dide, Awa f'ohun…
AWA l'Ẹgbẹ Kérúbù Séráfù, T'Oluwa fun 'ra rẹ gbe dide, Awa f'ohun wa ke Alleluyah, Si Ọlọrun Awimayẹhun, Ajẹ kan ko to lati bori Ijọ yi, Oso kan ko to lati bori Ijọ yi, Oluwa fun 'ra rẹ ni Oluto wa, Awa Ẹgbẹ Séráfù ko jẹ f'esu laye. Ẹda le fẹ o, ki wọn korira rẹ; Ayé le bu ọ, ki wọn sepe fun ọ. Bi wọn se ju yi lọ, nitori ti Jesu; Ma wo bẹ, ma wo bẹ ) Ma wo bẹ, se'fẹ Oluwa ) 2 Ayọ ni ki eyi jẹ fun yin, Ẹyin ti Lusifa ti tẹ ba, Oluwa ran Ẹgbẹ Mimọ yi, Lati fi asẹ gbe yin dide; Ẹ mase fi aigbagbọ se'ra yin lese, Ẹni nla ni Jesu Olori Ijọ wa, Nitori na ki ẹ f'ọkan yin balẹ, K'ẹ 'mọ p'okunkun ko bori imọlẹ ri o Ẹda le fẹ o, ki wọn korira rẹ; Ayé le bu ọ, ki wọn sepe fun ọ. Bi wọn se ju yi lọ, nitori ti Jesu; Ma wo bẹ, ma wo bẹ ) Ma wo bẹ, se'fẹ Oluwa ) 2 Bi Jesibeli mo pe bẹni, Yoo ri f'oun niwaju Jehu, Ki ba ti le tiro k'o gun gẹgẹ, Tun bere pe s'alafia ni; Ẹni n s'ọta Ọlọrun t'o n wa 'alafia. Anfani kil'o wa ninu ajẹ sise, Ẹ tari rẹ lokiti fun aja jẹ; Awa Ẹgbẹ Keburu ko ni f'esu laye. Ẹda le fẹ o, ki wọn korira rẹ; Ayé le bu ọ, ki wọn sepe fun ọ. Bi wọn se ju yi lọ, nitori ti Jesu; Ma wo bẹ, ma wo bẹ ) Ma wo bẹ, se'fẹ Oluwa ) 2 Ka p'arapọ sisẹ Oluwa, Ninu Ẹgbẹ Mimọ Kérúbù; K'a mase ro p'ẹnikan kere, J'ẹni ti Oluwa le lọ; Ranti Alufa Eli pẹlu Samuel, Modikai pẹlu ayaba Esta, Meji pere yi t'ẹkọ fun Séráfù, Awa Ẹgbẹ Séráfù ko ni f'esu laye. Ẹda le fẹ o, ki wọn korira rẹ; Ayé le bu ọ, ki wọn sepe fun ọ. Bi wọn se ju yi lọ, nitori ti Jesu; Ma wo bẹ, ma wo bẹ ) Ma wo bẹ, se'fẹ Oluwa ) 2 Ki gbogbo asiwaju Ẹgbẹ, Mura silẹ de bibọ Jesu; Iroyin wọn ki se kekere, Niwaju itẹ Baba loke; Asaju to de 'bẹ to n pitan ara rẹ, Ki Jesu to le mọ pe asiwaju ni, Ki y'o wọ'nu ogo na pẹl' Oluwa Ẹda le fẹ o, ki wọn korira rẹ; Ayé le bu ọ, ki wọn sepe fun ọ. Bi wọn se ju yi lọ, nitori ti Jesu; Ma wo bẹ, ma wo bẹ ) Ma wo bẹ, se'fẹ Oluwa ) 2 Gbogbo ẹyin ajẹ at'oso, T'o wa n di'sẹ Oluwa lọwọ, T'Oluwa kilọ fun yin titi, Ti ẹ ko fẹ ronupiwada, Ranti orukọ t'a ko s'ẹgbẹ ogiri, Mene, Mene, Tekeli…
Hymn 500 – AWA l'Ẹgbẹ Kerubu Serafu | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia