Hymn 498 – ALA kan ti mo la loru yi | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "ALA kan ti mo la loru yi" (C&S Hymn #498, Yoruba). ALA kan ti mo la loru yi, Michaeli lo sọkalẹ wa; Mo ri pe o fọ…
ALA kan ti mo la loru yi, Michaeli lo sọkalẹ wa; Mo ri pe o fọ 'tẹgun esu; Ogo ni fun Jesu ni ọrun; Ka ba gbogbo Angeli, sọkan lati kọrin, To fi sẹgun goke re ọrun, Lẹhin t'O ti bori esu (2) Kérúbù pẹlu Séráfù, Ẹ mura kẹ damure yin; Isẹ Oluwa l'awa n jẹ, Awa ki yoo bẹru ẹnikan. Ka ba gbogbo Angeli, sọkan lati kọrin, To fi sẹgun goke re ọrun, Lẹhin t'O ti bori esu (2) A ki gbogb' awọn Leader wa, T'o wa ba wa se Ajọdun; Ki Ọlọrun ko mẹsẹ yin duro, Lati gba' de iye ni ọrun. Ka ba gbogbo Angeli, sọkan lati kọrin, To fi sẹgun goke re ọrun, Lẹhin t'O ti bori esu (2) A ki Mose Orimolade, Fun 'sẹ nla t'o se larin wa; K'Ọlọrun ko busi isẹ rẹ, Ade Ogo yoo jẹ tirẹ. Ka ba gbogbo Angeli, sọkan lati kọrin, To fi sẹgun goke re ọrun, Lẹhin t'O ti bori esu (2) AMIN Ka ba gbogbo Angeli, sọkan lati kọrin, To fi sẹgun goke re ọrun, Lẹhin t'O ti bori esu (2)
Hymn 498 – ALA kan ti mo la loru yi | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia