Hymn 497 – Egbe Aladura mura | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "Egbe Aladura mura" (C&S Hymn #497, Yoruba). Ẹgbẹ Aladura mura; Lati pade Kérúbù; Jesu lo pe yin lo yan yin, Oun lo…
Ẹgbẹ Aladura mura; Lati pade Kérúbù; Jesu lo pe yin lo yan yin, Oun lo da'jọ yi silẹ, O si pe gbogbo ayé; Lati w'ọkọ 'gbala yi, Jesu mu wa de'tẹ ogo. B'ọjọ wa ti n kọja lọ. Ọjọ n lọ, ọjọ n lọ (2) Isẹ pọ t'awa yoo se, B'ọjọ wa ti n kọja lọ. Ẹgbẹ Séráfù d'amure, Lati pade Kérúbù, Ẹ ma jẹ k'amure yin tu, Lati pade Kérúbù, Gbe ida 'sẹgun soke, Iye s'Ọlọrun Daniel, Alleluya Jesu mbọ, B'ọjọ wa ti n kọja lọ. Ọjọ n lọ, ọjọ n lọ (2) Isẹ pọ t'awa yoo se, B'ọjọ wa ti n kọja lọ. Ọlọrun Mẹtalọkan wa, Lati gbọ adura mi, Jesu Olugbala mi wa, Lati gb'ẹbọ ọpẹ mi, Ẹmi Mimọ sọkalẹ, F'ore-ọfẹ ba wa gbe, Isẹ pọ t'awa o se, B'ọjọ wa ti n kọja lọ. Ọjọ n lọ, ọjọ n lọ (2) Isẹ pọ t'awa yoo se, B'ọjọ wa ti n kọja lọ. F'okun 'fẹ so gbogbo wa pọ B'ọjọ wa ti n kọja lọ, Kọkan la o fa wọn s'agbo wa B'ọjọ wa ti n kọja lọ, Sugbọn 'kore ti a gbin, L'ọsan at'oru yoo hu, Gb'awọn to subu dide, B'ọjọ wa ti n kọja lọ. Ọjọ n lọ, ọjọ n lọ (2) Isẹ pọ t'awa yoo se, B'ọjọ wa ti n kọja lọ. AMIN Ọjọ n lọ, ọjọ n lọ (2) Isẹ pọ t'awa yoo se, B'ọjọ wa ti n kọja lọ.
Hymn 497 – Egbe Aladura mura | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia