Hymn 490 – 'WỌ orisun ohun rere | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "'WỌ orisun ohun rere" (C&S Hymn #490, Yoruba). 'WỌ orisun ohun rere, Awa fẹ se'fẹ rẹ; Ohun wo l'a le fifun Ọ Ọba…
'WỌ orisun ohun rere, Awa fẹ se'fẹ rẹ; Ohun wo l'a le fifun Ọ Ọba gbogbo ayé? L'ayé yi, 'Wọ ni otosi, T'o jẹ eniyan Rẹ; Orukọ wọn n'Iwọ n jẹwọ, Niwaju Baba Rẹ. 'Gba wọn ba n ke n'inira wọn, Ohun Rẹ l'awa n gbọ; 'Gba ba si n se itọju wọn, Awa n se 'tọju Rẹ. Jesu, ma sai gba ọrẹ wa, Si f'ibukun Rẹ si; Ma f'ibukun Rẹ s'ẹbun wa Fun awọn t'a n fi fun. Fun Baba, Ọmọ at'Ẹmi, Ọlọrun ti a n sin; f Ni ki a ma fi ogo fun, Titi ayérayé. AMIN
Hymn 490 – 'WỌ orisun ohun rere | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia