Hymn 489 – OLORUN opo arugbo | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "OLORUN opo arugbo" (C&S Hymn #489, Yoruba). ỌLỌRUN ọpọ arugbo; T'ayé ro pe ko le bimọ mọ, N'Iwọ se l'ogo to bimọ, O si…

Hymn 489 – OLORUN opo arugbo | C&S Yoruba Hymnary
ỌLỌRUN ọpọ arugbo; T'ayé ro pe ko le bimọ mọ, N'Iwọ se l'ogo to bimọ, O si d'oju t'awọn ọta rẹ Gbọ temi, gbọ temi, Gbọ temi, Ọba awimayẹhun, Gbọ temi, gbọ temi, Gbọ temi, Ọba awimayẹhun. O s'arugbo di wundia, Ọlọrun to la sarah lagan, Ko ku, ko sa, O wa nibẹ; Baba, se 'ranlọwọ wa loni. Gbọ temi, gbọ temi, Gbọ temi, Ọba awimayẹhun, Gbọ temi, gbọ temi, Gbọ temi, Ọba awimayẹhun. Sarah fẹrẹ ma tun le gba, Pe 'ru oun tun le bimọ mọ, Lo fi rẹrin ninu ọkan; Sugbọn Ọlọrun ko ka s'ẹsẹ fun. Gbọ temi, gbọ temi, Gbọ temi, Ọba awimayẹhun, Gbọ temi, gbọ temi, Gbọ temi, Ọba awimayẹhun. Okiki Ọlọrun mi kan, Oju mi ko ri 'ru eyi ri, T'igi t'ọpẹ lo n damuso, Fun iloyun Elisabeth. Gbọ temi, gbọ temi, Gbọ temi, Ọba awimayẹhun, Gbọ temi, gbọ temi, Gbọ temi, Ọba awimayẹhun. Hihu agbado ki tase, Hihu ọka ki tase; Mase jẹ ki arabinrin yi, Tase ọmọ rere lọdọ Rẹ. Gbọ temi, gbọ temi, Gbọ temi, Ọba awimayẹhun, Gbọ temi, gbọ temi, Gbọ temi, Ọba awimayẹhun. Baba, Ọmọ, Ẹmi Mimọ , Ko s'awati ore lọdọ Rẹ, Ma jẹ k'oso, ajẹ dina, Lati f'arabinrin yi l'ọmọ. Gbọ temi, gbọ temi, Gbọ temi, Ọba awimayẹhun, Gbọ temi, gbọ temi, Gbọ temi, Ọba awimayẹhun. AMIN Gbọ temi, gbọ temi, Gbọ temi, Ọba awimayẹhun, Gbọ temi, gbọ temi, Gbọ temi, Ọba awimayẹhun.

Hymn 489 – OLORUN opo arugbo | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia