Hymn 487 – O ti wu mi pupo | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "O ti wu mi pupo" (C&S Hymn #487, Yoruba). O ti wu mi pupọ, Ọmọ mi wa; Emi mo n pese rẹ, Sugbọn mo fẹ j'afẹ, Niwọn t'o…

Hymn 487 – O ti wu mi pupo | C&S Yoruba Hymnary
O ti wu mi pupọ, Ọmọ mi wa; Emi mo n pese rẹ, Sugbọn mo fẹ j'afẹ, Niwọn t'o ba wu mi, Emi si tilẹ fẹ, Foriti sibẹ sibẹ. Ọlọrun, saanu mi, Jọwọ saanu mi (2) Iwọ alaanu julọ; Jọwọ saanu mi, Iwọ l'aanu julọ. Kérúbù ati Séráfù, Ẹ mura si 'sẹ, K'ẹ si ma gbadura, Ọlọrun Mose, Ati ti Elijah, Emi si tilẹ fẹ, Foriti sibẹ sibẹ. Ọlọrun, saanu mi, Jọwọ saanu mi (2) Iwọ alaanu julọ; Jọwọ saanu mi, Iwọ l'aanu julọ. Baba Aladura, Ẹ ku isẹ ẹmi; Ade iye yoo jẹ; Tirẹ titi ayé; Emi si tilẹ fẹ, Foriti sibẹ-sibẹ Ọlọrun, saanu mi, Jọwọ saanu mi (2) Iwọ alaanu julọ; Jọwọ saanu mi, Iwọ l'aanu julọ. AMIN Ọlọrun, saanu mi, Jọwọ saanu mi (2) Iwọ alaanu julọ; Jọwọ saanu mi, Iwọ l'aanu julọ.

Hymn 487 – O ti wu mi pupo | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia