Hymn 486 – OHUN t'a fi fun O | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "OHUN t'a fi fun O" (C&S Hymn #486, Yoruba). OHUN t'a fi fun Ọ Tirẹ ni Oluwa: Gbogbo ohun ti a si ni, Ọwọ Rẹ lo ti wa.…

Hymn 486 – OHUN t'a fi fun O | C&S Yoruba Hymnary
OHUN t'a fi fun Ọ Tirẹ ni Oluwa: Gbogbo ohun ti a si ni, Ọwọ Rẹ lo ti wa. Jẹ k'a gba ẹbun Rẹ, Bi iriju rere; Bi O si ti mbukun wa to, Bẹ l'a o fi fun Ọ. Ọpọ ni isẹ n sẹ, Ti wọn ko r'Ounjẹ jẹ; Ọpọ l'o si ti sako lọ, Kuro l'agbo Jesu. K'a ma tu ni ninu, K'a ma rẹ ni l'ẹkun, K'a ma bọ alainibaba, N'ise t'a ba ma se. K'a tu onde silẹ, K'a f'ọna iye han, K'a kọ ni lọna Ọlọrun, B'iwa Kristi lo ri. A gba ọrọ Rẹ gbọ, Busi igbagbọ wa; f Ohun t'a se fun ẹni Rẹ, Jesu, a se fun Ọ. AMIN

Hymn 486 – OHUN t'a fi fun O | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia