Hymn 480 – B' IJI lile n ja t'ibẹru gb'ode | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "B' IJI lile n ja t'ibẹru gb'ode" (C&S Hymn #480, Yoruba). B' IJI lile n ja t'ibẹru gb'ode, T'ore gbogbo lọ, t'ọta si…

Hymn 480 – B' IJI lile n ja t'ibẹru gb'ode | C&S Yoruba Hymnary
B' IJI lile n ja t'ibẹru gb'ode, T'ore gbogbo lọ, t'ọta si gbogun, Ohun to wu ko de ifoya ko si, Ileri rẹ ni, Oluwa yoo pese. Ẹyẹ ki n sisẹ, wọn ri Ounjẹ jẹ, O yẹ k'a f'eyi s'ẹkọ fun ra wa, Awọn ayanfẹ Rẹ ki y'o s'alaini. A ti kọwe rẹ p'Oluwa y'o pese. Gbat' ogun esu n fẹ de wa lọna, T'ibẹru si fẹ bori 'gbagbọ wa; Ko le pa gbolohun yi da l'ọkan wa Ileri ifẹ Oluwa yoo pese. Ki s'agbara wa tab' ise wa, Orukọ Jesu ni 'gbẹkẹle wa, Kérúbù Séráfù, ẹ ma bohun bọ N' ijakadi yin, Oluwa yoo pese. Gbat' iku ba de t'ẹmi si n lọ, Ọrọ 'tunu Rẹ y'o mu wa laja; Gba Kristi wa lọdọ wa ifoya ko si, A o ma kọrin Oluwa yoo pese. Ogo fun Baba, Ogo fun Ọmọ, Ogo f'Ẹmi Mimọ Mẹtalọkan L'agbara Ẹlẹda ọrun oun ayé, Jehovah Jire Oluwa yoo pese. AMIN

Hymn 480 – B' IJI lile n ja t'ibẹru gb'ode | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia