Hymn 448 – EYIN Omo Egbe Kerubu | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "EYIN Omo Egbe Kerubu" (C&S Hymn #448, Yoruba). ẸYIN Ẹgbẹ Ijọ Kérúbù, Ma bẹru, ma sojo; Oluwa l'o n ran wa n'isẹ, Awa…

Hymn 448 – EYIN Omo Egbe Kerubu | C&S Yoruba Hymnary
ẸYIN Ẹgbẹ Ijọ Kérúbù, Ma bẹru, ma sojo; Oluwa l'o n ran wa n'isẹ, Awa ki yoo bẹru. Bayé n sata pẹlu esu, Eke ni wọn, wọn n se lasan, Bayé n sata pẹlu esu, Eke ni wọn, wọn n se lasan Ẹyin Ọmọ Ẹgbẹ Séráfù, Ma jẹ k'oju ti yin, Isẹ Oluwa l'awa n jẹ, Awa ki yoo tiju Bayé n sata pẹlu esu, Eke ni wọn, wọn n se lasan, Bayé n sata pẹlu esu, Eke ni wọn, wọn n se lasan Ẹyin Ẹgbẹ Aladura, Ẹ mura s'isẹ yin, Gbogbo isẹ yin ti ẹ n se, Ọkan ko lọ lasan. Bayé n sata pẹlu esu, Eke ni wọn, wọn n se lasan, Bayé n sata pẹlu esu, Eke ni wọn, wọn n se lasan Ẹyin Ọmọ Ẹgbẹ Bibeli, Ẹ mura s'adura, K'Ọlọrun la oju ẹmi yin, Lati rohun ijinlẹ. Bayé n sata pẹlu esu, Eke ni wọn, wọn n se lasan, Bayé n sata pẹlu esu, Eke ni wọn, wọn n se lasan Ẹyin Ọmọ Ẹgbẹ Akọrin, Ẹ tun ohun yin se, Orin l'awa yoo kọ lọrun, A ko n'isẹ miran. Bayé n sata pẹlu esu, Eke ni wọn, wọn n se lasan, Bayé n sata pẹlu esu, Eke ni wọn, wọn n se lasan Ẹ f'ogo fun Mẹtalọkan, Baba Ọmọ, Ẹmi, Titi ayé ainipẹkun, Amin! bẹni ki o ri. Bayé n sata pẹlu esu, Eke ni wọn, wọn n se lasan, Bayé n sata pẹlu esu, Eke ni wọn, wọn n se lasan AMIN Bayé n sata pẹlu esu, Eke ni wọn, wọn n se lasan, Bayé n sata pẹlu esu, Eke ni wọn, wọn n se lasan

Hymn 448 – EYIN Omo Egbe Kerubu | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia