Hymn 446 – Alafia, ni aye ese yi | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "Alafia, ni aye ese yi" (C&S Hymn #446, Yoruba). Alafia, ni ayé ẹsẹ yi? Ẹjẹ Jesu n wi pé, ―Alafia‖ Alafia, ninu ọpọ…
Alafia, ni ayé ẹsẹ yi? Ẹjẹ Jesu n wi pé, ―Alafia‖ Alafia, ninu ọpọ lala? Lati se ifẹ Jesu, ni 'sinmi. Alafia, n'nu igbi 'banujẹ? L'aya Jesu ni dakẹ rọrọ wa. Alafia, gb'ara wa wa l'ajo? Ni 'pamọ Jesu, ibẹru ko si. Alafia, b'a ko tilẹ m'ọla? Sugbọn a mọ pe Jesu wa lailai. Alafia, nigb' akoko iku? Olugbala wa ti sẹgun iku. O to: jakadi ayé fere pin, Jesu y'o pe wa s'ọrun alafia. AMIN
Hymn 446 – Alafia, ni aye ese yi | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia