Hymn 442 – A ba le n'igbagbo aye | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "A ba le n'igbagbo aye" (C&S Hymn #442, Yoruba). A ba le n'igbagbọ aye, B'o ti wu k'ọta pọ; Igbagbọ ti ko jẹ mira, Fun…
A ba le n'igbagbọ aye, B'o ti wu k'ọta pọ; Igbagbọ ti ko jẹ mira, Fun aini at'osi. Igbagbọ ti ko jẹ rahun , L'abẹ ibawi Rẹ, Sugbọn ti n sinmi l'Ọlọrun, Nigba ibanujẹ. Igbagbọ ti n tan siwaju, Gbat' iji 'pọnju de; Ti ko si jẹ siyemeji, N'nu wahala gbogbo. Igbagbọ ti n gb'ọna toro Titi ẹmi o pin, Ti y'o si f'imọlẹ ọrun, Tan akete iku. Jesu f'igbagbọ yi fun mi; Njẹ b'o ti wu k'o ri, Lat' ayé yi lọ n ó l'ayọ, Ilu ọrun rere. AMIN
Hymn 442 – A ba le n'igbagbo aye | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia