Hymn 441 – GBOGB' eyin Onigbagbo | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "GBOGB' eyin Onigbagbo" (C&S Hymn #441, Yoruba). GBOGB' ẹyin Onigbagbọ, To wa lode ayé, Babalawo gbe 'fa wa, O tun…

Hymn 441 – GBOGB' eyin Onigbagbo | C&S Yoruba Hymnary
GBOGB' ẹyin Onigbagbọ, To wa lode ayé, Babalawo gbe 'fa wa, O tun d'Aladura. Ẹ yi pada, Ọjọ 'dajọ de tan, Ẹ yi pada, ẹ sunmọ Ọlọrun Pupọ abọgi bọ'pẹ Fori balẹ f'Ọba, Wọn si tun jẹri Kristi, Niwaj' onigbagbọ. Ẹ yi pada, Ọjọ 'dajọ de tan, Ẹ yi pada, ẹ sunmọ Ọlọrun Ọrọ Olugbala se, Lori gbogbo ayé, Wi pé gbogbo ekun ni Yoo wolẹ fun mi. Ẹ yi pada, Ọjọ 'dajọ de tan, Ẹ yi pada, ẹ sunmọ Ọlọrun Sib' awọn onigbagbọ, Gb'ohun asan dani, T'o ni ohun 'dile ni, Emi ko le s'aise. Ẹ yi pada, Ọjọ 'dajọ de tan, Ẹ yi pada, ẹ sunmọ Ọlọrun Itiju pupọ yoo wa, F'awọn onigbagbọ, At'awọn onimale, Gb'onifa ba wọle. Ẹ yi pada, Ọjọ 'dajọ de tan, Ẹ yi pada, ẹ sunmọ Ọlọrun Ọkunrin at' obinrin, T'o wa nin' Ẹgbẹ yi, Isẹ pọ pupọ l'oke, Tal' awa yoo ran lọ. Ẹ yi pada, Ọjọ 'dajọ de tan, Ẹ yi pada, ẹ sunmọ Ọlọrun O seun ọmọ rere, L'ohun 'kẹhin yoo jẹ, F'awọn to s'olotitọ, 'Nu Ijọ Kérúbù. Ẹ yi pada, Ọjọ 'dajọ de tan, Ẹ yi pada, ẹ sunmọ Ọlọrun Ẹ lọ kuro lọdọ mi, Emi ko mọ yin ri, L'ohun ikẹhin yoo jẹ, F'awọn alaigbagbọ. Ẹ yi pada, Ọjọ 'dajọ de tan, Ẹ yi pada, ẹ sunmọ Ọlọrun Jehovah Jire Baba, Jọwọ pese fun wa, Jehovah Nisi Baba, Pa wa mọ de opin. Ẹ yi pada, Ọjọ 'dajọ de tan, Ẹ yi pada, ẹ sunmọ Ọlọrun AMIN Ẹ yi pada, Ọjọ 'dajọ de tan, Ẹ yi pada, ẹ sunmọ Ọlọrun

Hymn 441 – GBOGB' eyin Onigbagbo | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia