Hymn 439 – OLUWA l'oluso mi emi ki o s'alaini | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "OLUWA l'oluso mi emi ki o s'alaini" (C&S Hymn #439, Yoruba). OLUWA l'oluso mi emi ki o s'alaini, Jesu l'oluso aguntan…

Hymn 439 – OLUWA l'oluso mi emi ki o s'alaini | C&S Yoruba Hymnary
OLUWA l'oluso mi emi ki o s'alaini, Jesu l'oluso aguntan ọmọ Re, O mu mi sun ni papa oko tutu to dara, O tu ara ati okan mi lara. Damuso fun Baba, Awa ma ridi jinle, Kabiyesi, Mesaiah mimo jowo mase le mi lodo Re, Nipa ore-ọfẹ Re ki n le de 'be. Bi mo tilẹ n kọja lọ larin afonifoji, T'o kun fun banujẹ at'ọpọ 'damu, Emi ki o si bẹru ohunkohun to le de, Tori Oluwa ogo wa pẹlu mi. Damuso fun Baba, Awa ma ridi jinle, Kabiyesi, Mesaiah mimo jowo mase le mi lodo Re, Nipa ore-ọfẹ Re ki n le de 'be. Iwọ fun mi ni Ounjẹ loju awọn ọta mi, O da ororo 'fẹ Rẹ si mi lori, Ire anu at'ayọ yo ma ba mi gbe titi, N ó si ma yin O Oluwa titi lai. Damuso fun Baba, Awa ma ridi jinle, Kabiyesi, Mesaiah mimo jowo mase le mi lodo Re, Nipa ore-ọfẹ Re ki n le de 'be. Ọlọrun ayérayé to da orun at'ayé, Awa juba Rẹ Ẹlẹda alaye, F'anu Rẹ lori awa ẹda, ọwọ Rẹ layé, F'abo to fi ń bo wa ni ọjọ gbogbo. Damuso fun Baba, Awa ma ridi jinle, Kabiyesi, Mesaiah mimo jowo mase le mi lodo Re, Nipa ore-ọfẹ Re ki n le de 'be. A f'ogo f'orukọ Rẹ, Jehovah mimọ loke, Jesu Ọmọ mimọ to ra wa pada, A f'ogo f'Ẹmi Mimọ to sọ wa d'ẹni iye Ogo f'ologo Mẹtalọkan lailai. Damuso fun Baba, Awa ma ridi jinle, Kabiyesi, Mesaiah mimo jowo mase le mi lodo Re, Nipa ore-ọfẹ Re ki n le de 'be. AMIN Damuso fun Baba, Awa ma ridi jinle, Kabiyesi, Mesaiah mimo jowo mase le mi lodo Re, Nipa ore-ọfẹ Re ki n le de 'be.

Hymn 439 – OLUWA l'oluso mi emi ki o s'alaini | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia