Hymn 438 – Ore bi Jesu ko si l'ayé yi | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "Ore bi Jesu ko si l'ayé yi" (C&S Hymn #438, Yoruba). Ọrẹ bi Jesu ko si l'ayé yi, Oun nikan l'ọrẹ otitọ; Ọrẹ ayé yi le…
Ọrẹ bi Jesu ko si l'ayé yi, Oun nikan l'ọrẹ otitọ; Ọrẹ ayé yi le kọ wa silẹ; Sugbọn Jesu ko jẹ gbagbe mi A! ko jẹ gbagbe mi! A! ko jẹ gbagbe mi! Sugbọn Jesu ko jẹ gbagbe mi. Duro d'Oluwa, ma siyemeji, Ohunkohun to wu ko le de, 'Gbati o ro pin, 'ranwọ Rẹ yoo de, Ẹni 'yanu l'Ọba Oluwa. A! ko jẹ gbagbe mi! A! ko jẹ gbagbe mi! Sugbọn Jesu ko jẹ gbagbe mi. Ẹyin Alagba at'Aladura, Ati gbogbo Ẹgbẹ Ojise; Onidajọ mbo gọngọ yoo sọ, Awawi kan ko si lọjọ na. A! ko jẹ gbagbe mi! A! ko jẹ gbagbe mi! Sugbọn Jesu ko jẹ gbagbe mi. Ẹyin ọm'Ẹgbẹ Akọrin 'bilẹ, Ati gbogbo Ẹgbẹ Akọrin, Olugbala mbọ lati pin ere, O daju pe ko jẹ gbagbe mi. A! ko jẹ gbagbe mi! A! ko jẹ gbagbe mi! Sugbọn Jesu ko jẹ gbagbe mi. Ọjọ mbọ t'a o dan 'gbagbọ yin wo, Kérúbù oun Séráfù t'ayé, Ina l'a o fi dan 'gbagbọ yin wo, T'ẹni to ba jona padanu. A! ko jẹ gbagbe mi! A! ko jẹ gbagbe mi! Sugbọn Jesu ko jẹ gbagbe mi. Ogo ni fun Baba, Ogo fun Ọmọ, Ogo si ni fun Ẹmi Mimọ ; A o fi ogo fun Mẹtalọkan, O daju pe ko jẹ gbagbe mi. A! ko jẹ gbagbe mi! A! ko jẹ gbagbe mi! Sugbọn Jesu ko jẹ gbagbe mi. AMIN A! ko jẹ gbagbe mi! A! ko jẹ gbagbe mi! Sugbọn Jesu ko jẹ gbagbe mi.
Hymn 438 – Ore bi Jesu ko si l'ayé yi | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia