Hymn 433 – OLUWA f'ise ran mi, Alleluya | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "OLUWA f'ise ran mi, Alleluya" (C&S Hymn #433, Yoruba). OLUWA f'isẹ ran mi, Alleluya, Emi yio jẹ'sẹ na fun ọ; O wa ninu…

Hymn 433 – OLUWA f'ise ran mi, Alleluya | C&S Yoruba Hymnary
OLUWA f'isẹ ran mi, Alleluya, Emi yio jẹ'sẹ na fun ọ; O wa ninu Ọrọ Rẹ, Alleluya Wo Jesu nikansoso k'o ye Wo k'o ye ara mi ye, Boju wo Jesu k'o ye, Isẹ lat'oke wa ni, Alleluya Ẹ jẹ k'a wo Jesu k'a si ye. Isẹ na kun fun ifẹ, Alleluya Fun ẹyin ara ilu Eko, Isẹ lat'oke wa ni Alleluya, At'awọn t'o wa n'ilu oke Wo k'o ye ara mi ye, Boju wo Jesu k'o ye, Isẹ lat'oke wa ni, Alleluya Ẹ jẹ k'a wo Jesu k'a si ye. Gbogbo Ẹgbẹ agbayé, Alleluya, Jesu n ke tantan wi pé ma bọ, Igbala l'ọfẹ d'ode, Alleluya, Jẹ k'a juba Jesu k'a si ye. Wo k'o ye ara mi ye, Boju wo Jesu k'o ye, Isẹ lat'oke wa ni, Alleluya Ẹ jẹ k'a wo Jesu k'a si ye. Jesu Olugbala wa, Alleluya, A f'ogo f'orukọ Mimọ Rẹ, Fun idasi wa loni, Alleluya; Iyin fun Mẹtalọkan lailai. Wo k'o ye ara mi ye, Boju wo Jesu k'o ye, Isẹ lat'oke wa ni, Alleluya Ẹ jẹ k'a wo Jesu k'a si ye. Kérúbù oun Séráfù, Alleluya, Ẹ ja titi d'opin emi yin; K'a le gba ade iye, Alleluya Lọdọ Baba loke lohun. Wo k'o ye ara mi ye, Boju wo Jesu k'o ye, Isẹ lat'oke wa ni, Alleluya Ẹ jẹ k'a wo Jesu k'a si ye. AMIN Wo k'o ye ara mi ye, Boju wo Jesu k'o ye, Isẹ lat'oke wa ni, Alleluya Ẹ jẹ k'a wo Jesu k'a si ye.

Hymn 433 – OLUWA f'ise ran mi, Alleluya | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia