Hymn 432 – Ma gbadura; Emi mbebe N'nu re | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "Ma gbadura; Emi mbebe N'nu re" (C&S Hymn #432, Yoruba). Ma gbadura; Ẹmi mbẹbẹ N'nu rẹ Fun gbogbo aini rẹ igba gbogbo…
Ma gbadura; Ẹmi mbẹbẹ N'nu rẹ Fun gbogbo aini rẹ igba gbogbo Ma gbadura; labẹ ẹru ẹsẹ, Adura n ri ẹjẹ Jesu ti n san. Ma gbadura; b'arẹ tilẹ mu Adura n gbe wa s'ẹba 'tẹ Baba. Ma gbadura; n'nu wahala ayé, Adura l'o n fun ọkan n'isinmi. Ma gbadura, b'ayọ ba yi ọ ka, Adura n lu harp, o n kọrin Angẹl Ma gbadura, b'awọn t'o fẹran ku, Adura mba wọn mu omi iye. Gbogb' ohun ayé y'o b'ayé kọja, Adura wa titi: ma gbadura. AMIN
Hymn 432 – Ma gbadura; Emi mbebe N'nu re | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia