Hymn 426 – IWO Isun Imole | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "IWO Isun Imole" (C&S Hymn #426, Yoruba). IWỌ Isun Imọlẹ; Ogo ti ko l'okunkun, Ayérayé, titi lai, Baba Mimọ, gbọ tiwa.…
IWỌ Isun Imọlẹ; Ogo ti ko l'okunkun, Ayérayé, titi lai, Baba Mimọ, gbọ tiwa. Kanga iye ti n san lai; Iye ti ko l'abawọn, Iye to ni irora, Baba Mimọ, gbọ tiwa. Olubukun Olufẹ, Ọmọ Rẹ mbẹ Ọ loke; Ẹmi Rẹ n radọ bo wa; Baba Mimọ, gbọ tiwa. Y'itẹ safire Rẹ ka, L'osumare ogo n tan; O kun fun alafia, Baba Mimọ, gbọ tiwa. Niwaju 'tẹ anu Rẹ L'awọn Angeli n pade; Sugbọn wo wa lẹsẹ Rẹ, Baba Mimọ, gbọ tiwa. Iwọ ti ọkan Rẹ n yọ, S'amusua t'o pada, T'o mo 'rin rẹ lokere Baba Mimọ, gbọ tiwa. Ọkan ti n wa isinmi; Ọkan t'ẹru n pa; B'ọm'ọwọ ti n ke f'ọmu, Baba Mimọ, gbọ tiwa. Gbogbo wa ni alaini, L'ebi, l'oungbẹ at'arẹ; Ko si ede f'aini wa Baba Mimọ, gbọ tiwa. Isura ọpọlọpọ, Kọ lo kojọ bi Ọba? Ainiye, aidiyele? Baba Mimọ, gbọ tiwa. 'Wọ ko da ọmọ Rẹ si, Ọmọ Rẹ kansoso na, Tit' O fi par' isẹ Rẹ, Baba Mimọ, gbọ tiwa. AMIN
Hymn 426 – IWO Isun Imole | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia