Hymn 425 – JESU, nib'eni Re pade | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "JESU, nib'eni Re pade" (C&S Hymn #425, Yoruba). JESU, nib'ẹni Rẹ pade, Nibẹ, wọn r'itẹ anu Rẹ; Nibẹ, wọn wa Ọ, wọn ri…
JESU, nib'ẹni Rẹ pade, Nibẹ, wọn r'itẹ anu Rẹ; Nibẹ, wọn wa Ọ, wọn ri Ọ, Ibikibi n'ilẹ ọwọ. Ko s'ogiri t'o se Ọ mọ, O gbe inu onirẹlẹ, Wọn mu Ọ wa 'bi wọn ba wa 'Gba wọn n lọ'le wọn mu Ọ lọ. Olus'aguntan ẹni Rẹ, Sọ anu Rẹ 'gbani d'ọtun, Sọ adun orukọ nla Rẹ, Fun ọkan ti n wa oju Rẹ. Jẹ k'a r'ipa adua nihin, Lati sọ 'gbagbọ di lile, Lati gbe ifẹ wa soke: Lati gb'orun ka 'waju wa. Oluwa, 'Wọ wa nitosi, N'apa Rẹ de'ti Rẹ silẹ; Si ọrun sọkalẹ kankan; Se gbogbo ọkan ni Tirẹ. AMIN
Hymn 425 – JESU, nib'eni Re pade | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia