Hymn 399 – IWO Oro Olorun | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "IWO Oro Olorun" (C&S Hymn #399, Yoruba). IWỌ Ọrọ Ọlọrun, Ọgbọn at'oke wa, Otọ ti ki yipada, Imọlẹ ayé wa: Awa yin Ọ…
IWỌ Ọrọ Ọlọrun, Ọgbọn at'oke wa, Otọ ti ki yipada, Imọlẹ ayé wa: Awa yin Ọ fun 'mọlẹ, T'inu Iwe mimọ; Fitila fun ẹsẹ wa; Ti n tan titi ayé. Oluwa l'o f'ẹbun yi, Fun Ijọ Rẹ l'ayé, A n gbe 'mọlẹ na soke, Lati tan y'ayé ka, Apoti wura n'ise, O kun fun Otitọ; Aworan Kristi si ni; Ọrọ iye totọ. O n fẹ lẹlẹ b'asia, T'a ta loju ogun; O n tan b'ina alore; Si okunkun ayé, Amọna eniyan ni Ni wahala gbogbo, Nin' arin omi ayé; O n tọ wa sọdọ Krist. Olugbala, se 'jọ Rẹ, Ni fitila wura; Lati tan imọlẹ Rẹ, B'ayé igbani; Kọ awọn ti o sako, Lati lo 'mọlẹ yi; Tit' okun ayé y'o pin, Ti wọn o r'oju Rẹ. AMIN
Hymn 399 – IWO Oro Olorun | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia