Hymn 394 – Mo f'iyin ailopin | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "Mo f'iyin ailopin" (C&S Hymn #394, Yoruba). Mo f'iyin ailopin, Fun Ọlọrun Baba, Fun ore ayé mi, At' ireti t'ọrun, O…
Mo f'iyin ailopin, Fun Ọlọrun Baba, Fun ore ayé mi, At' ireti t'ọrun, O ran Ọmọ Rẹ ayanfẹ, Lati ku fun ẹsẹ ayé. Mo f'iyin ailopin Fun Ọlọrun Ọmọ, T'O f'ẹjẹ Rẹ wẹ wa, Kuro ninu egbe; Nisinsin yii O wa l'Ọba, O n ri eso irora Rẹ. Mo f'iyin ailopin, Fun Ọlọrun Ẹmi; Ẹni f'agbara Rẹ, So ẹlẹsẹ d'aye, O pari isẹ igbala, O si fi ayọ kun ọkan. Mo f'ọla ailopin, Fun Olodumare, 'Wọ Ologo mẹta, Sugbọn ọkansoso B'O ti ju imọ wa lo ni, A o ma f'igbagbọ yin Ọ. AMIN
Hymn 394 – Mo f'iyin ailopin | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia