Hymn 393 – Olorun Olodumare | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "Olorun Olodumare" (C&S Hymn #393, Yoruba). Ọlọrun Olodumare, Baba, Ọmọ, Ẹmi, Riri ẹni t'a ko le mọ, Ẹni t'a ko le ri.…
Ọlọrun Olodumare, Baba, Ọmọ, Ẹmi, Riri ẹni t'a ko le mọ, Ẹni t'a ko le ri. Ye! Baba Olodumare, K'a wariri fun Ọ, Ni gbogbo orilẹ ede, Ni a o ma sin Ọ. Ọlọrun Ọmọ, Ọrẹ wa, 'Wọ t'o ra wa pada, Ma jọwọ wa, Olugbala! Gba wa patapata. A! Ọlọrun Ẹmi Mimọ , 'Wọ olore-ọfẹ, A bẹ Ọ, fun wa ni imọ, K'a m'Ọlọrun n'ifẹ. Ọkansoso sugbọn mẹta, Ẹmi Mẹtalọkan, Ọlọrun awamaridi, Ẹni Mẹtalọkan! AMIN
Hymn 393 – Olorun Olodumare | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia