Hymn 338 – 'BUGBE Re ti l'ewa to | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "'BUGBE Re ti l'ewa to" (C&S Hymn #338, Yoruba). 'BUGBE Rẹ ti l'ẹwa to! Ni'lẹ 'molẹ at'ifẹ; 'Bugbe Rẹ ti l'ẹwa to! Layé…

Hymn 338 – 'BUGBE Re ti l'ewa to | C&S Yoruba Hymnary
'BUGBE Rẹ ti l'ẹwa to! Ni'lẹ 'molẹ at'ifẹ; 'Bugbe Rẹ ti l'ẹwa to! Layé ẹsẹ at'osi; Ọkan mi n fa nitotọ, Fun idapọ eniyan Rẹ, Fun imọlẹ oju Rẹ, Fun ẹkun Rẹ Ọlọrun. Ayọ ba awọn ẹyẹ, Ti n fo yi pẹpẹ Rẹ ka; Ayọ ọkan t'o sinmi L'ayé Baba l'o pọju! Gẹgẹ b'adaba Noa, Ti ko r'ibi sinmi le, Wọn pada sọdọ Baba, Wọn si n yọ titi ayé. Wọn ko sinmi iyin wọn, Ninu ayé osi yi; Omi n sun ni aginju, Manna n t'ọrun wa fun wọn, Wọn n lọ lat'ipa de'pa, Titi wọn fi yọ si Ọ; Wọn si wolẹ l'ẹsẹ Rẹ, T'O mu wọn la ewu ja. Baba, jẹ ki n jere bẹ, S'amọna mi l'ayé yi, F'ore ọfẹ pa mi mọ, Fun mi l'aye lọdọ Rẹ; Iwọ l'Ọrun at'Asa, Tọ ọkan isina mi; Iwọ l'orisun oore; Rọ ojo rẹ sori mi. AMIN

Hymn 338 – 'BUGBE Re ti l'ewa to | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia