Hymn 337 – KI NI 'Sinmi ayo ailopin ni | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "KI NI 'Sinmi ayo ailopin ni" (C&S Hymn #337, Yoruba). KI NI 'Sinmi ayọ ailopin ni, T'awọn Angẹl' at'awọn mimọ ni?…
KI NI 'Sinmi ayọ ailopin ni, T'awọn Angẹl' at'awọn mimọ ni? 'Sinmi f'alarẹ, f'awọn asẹgun, Nibẹ l'Ọlọrun jẹ ohun gbogbo. Tal' Ọba na? Tani yi 'tẹ rẹ ka? Irora itura Rẹ ha ti ri? Sọ funni, ẹyin ti n jọsin nibẹ; Sọ funni, b'ọrọ to t'ayọ yin sọ. Jerusalem totọ, ilu mimọ, Alafia eyi t'o jẹ kik'ayọ A r'ohun t'a n fẹ n'nu Rẹ K'a to wi, A si ri gba ju eyi t'a n fẹ lọ. L'agbala Ọba wa, wahala tan, Laibẹru l'a o ma kọrin Sion, Oluwa, niwaju Rẹ l'a o ma fi, Idahun 'fẹ han f'ẹbun ifẹ rẹ. 'Sinmi ko to tẹle s' mi nibẹ, Ẹnikan ni 'sinmi ti n woju Rẹ, Nibẹ orin jubeli ko le tan, T'awọn mimọ at'angẹli y'o kọ. Layé yi pẹlu 'gbagbọ at'adua, L'a o ma safẹri 'le Baba ohun, Si Salem l'awọn ti a si nipo, N pada lọ; lat'ilu Babiloni. Njẹ awa tẹriba niwaju Rẹ, T'Ẹni ti ohun gbogbo ja si, Ninu ẹni ti Baba at'Ọmọ, T'ẹni ti Emi jẹ Ọkansoso. AMIN
Hymn 337 – KI NI 'Sinmi ayo ailopin ni | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia