Hymn 332 – MO wi fun olukuluku | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "MO wi fun olukuluku" (C&S Hymn #332, Yoruba). MO wi fun olukuluku, Pe, Oun ji, O si ye; O si wa larin wa pẹlu, Nipa…

Hymn 332 – MO wi fun olukuluku | C&S Yoruba Hymnary
MO wi fun olukuluku, Pe, Oun ji, O si ye; O si wa larin wa pẹlu, Nipa Ẹmi iye. Ẹ wi fun ẹnikeji yin, Ki wọn ji pẹlu wa, K'imọlẹ k'o wa kakiri, Ni gbogbo ayé wa. Nisinsin yii ayé yi ri, Bi ile Baba wa; Iye titun ti Oun fun ni, O sọ d'ile Baba. Ọna okun ti Oun ti rin, Mu ni lọ si ọrun: Ẹni t'o rin bi Oun ti rin, Y'o d'ọdọ Rẹ l'ọrun Oun ye, O si wa pẹlu wa, Ni gbogbo ayé yi: Ati nigba ti a f'ara wa, F'erupẹ ni 'reti. AMIN

Hymn 332 – MO wi fun olukuluku | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia