Hymn 331 – Jesu ore elese ku | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "Jesu ore elese ku" (C&S Hymn #331, Yoruba). Jesu ọrẹ ẹlẹsẹ ku, Awọn ọmọ Salem n sọkun: Okunkun bo oju ọrun, Isẹlẹ nla…

Hymn 331 – Jesu ore elese ku | C&S Yoruba Hymnary
Jesu ọrẹ ẹlẹsẹ ku, Awọn ọmọ Salem n sọkun: Okunkun bo oju ọrun, Isẹlẹ nla sẹ lojiji. Nihin l'a r'anu at'ifẹ, Ọba ogo ku f'eniyan; Wa! Ayọ kil' a tun ri yi, Jesu t'O ku tun ji dide. Ma bẹru mọ, ẹyin mimọ; Sọ bi Oluwa ti jọba; Kọrin b'O ti sẹgun Esu, Bi O si ti bori iku. Ẹ wi pé, ―Ọba, wa titi, Iwọ t'a bi lati gba wa, K'ẹ b'iku pe, ―oro rẹ da? Iboji, isẹgun rẹ da? AMIN

Hymn 331 – Jesu ore elese ku | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia