Hymn 32 – EYI l'ojo t'oluwa da | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "EYI l'ojo t'oluwa da" (C&S Hymn #32, Yoruba). 1. EYI l'ọjọ t'Oluwa da, O pe 'gba na n tire; K'ọrun k'o yọ, k'ayé ko…

Hymn 32 – EYI l'ojo t'oluwa da | C&S Yoruba Hymnary
1. EYI l'ọjọ t'Oluwa da, O pe 'gba na n tire; K'ọrun k'o yọ, k'ayé ko yọ, K'iyin yi'tẹ naa ka. 2. Loni, o jinde 'nu oku, Ijọba Satan tu: 'Wọn mimọ tan 'sẹgun Rẹ ka, Wọn n sọrọ 'yanu Rẹ. 3. Hosanna si Ọba t'a yan, S'Ọmọ mimọ Dafid: Oluwa, jọ sọkalẹ wa, T'Iwọ t'igbala Rẹ. 4. Abukun l'Oluwa t'o wa N'isẹ oore-ọfẹ, T'o wa l'orukọ Baba Rẹ, Lati gbà'ran wa là. 5. ff Hosanna ni ohun gooro, L'orin Ijọ t'ayé, Orin t'oke ọrun l'ọhun Yoo dun ju bẹ lọ. AMIN

Hymn 32 – EYI l'ojo t'oluwa da | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia