Hymn 031 – Bi mo ti yo lati gb'oro | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "Bi mo ti yo lati gb'oro" (C&S Hymn #031, Yoruba). 1. Bi mo ti yọ lati gb'ọrọ, Lẹnu awọn ọrẹ; Pe, ―Ni Sion ni k'a pe si…
1. Bi mo ti yọ lati gb'ọrọ, Lẹnu awọn ọrẹ; Pe, ―Ni Sion ni k'a pe si K'a p'ọjọ mimọ mọ 2. Mo f'ọna‘ta at'ẹkun rẹ, Ile t'a se lọsọ, Ile t'a kọ fun Ọlọrun Lati fi anu han. 3. S'agbala ile ayọ naa Lẹya mimọ si lọ, Ọmọ Dafid wa lor'itẹ O ń da ẹjọ nibẹ. 4. O gbọ iyin at'igbe wa; Bi ohun ẹru rẹ, Ti n ya ẹlẹsẹ sib'egbe, A ń yọ ni 'wariri. 5. K'ibukun pẹlu ibẹ na, Ayọ nigbakugba; K'a fi ọrẹ ati oore, F'awọn ti n sin nibẹ. 6. Ọkan mi bẹbẹ fun Sion Nigba ti emi wa; Nibẹ n'ibatan at'ọrẹ At'Olugbala wa. AMIN
Hymn 031 – Bi mo ti yo lati gb'oro | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia