Hymn 305 – OGO ni fun Jesu | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "OGO ni fun Jesu" (C&S Hymn #305, Yoruba). OGO ni fun Jesu, T'o f'irora nla, Ta ẹjẹ Rẹ fun mi, Lati iha Rẹ. Mo r'iye…

Hymn 305 – OGO ni fun Jesu | C&S Yoruba Hymnary
OGO ni fun Jesu, T'o f'irora nla, Ta ẹjẹ Rẹ fun mi, Lati iha Rẹ. Mo r'iye ailopin, Ninu ẹjẹ na; Iyọnu Rẹ sa pọ, Ore Rẹ ki tan. Ọpẹ ni titi lai, F'ẹjẹ 'yebiye, T'o ra ayé pada, Kuro n'nu egbe. Ẹjẹ Abel' ń kigbe, Si ọrun f'ẹsan; Sugb' ẹjẹ Jesu ń ke, Fun 'dariji wa. p Nigba ti a bu wọn, Ọkan ẹsẹ wa, Satan, n' idamu rẹ, F'ẹru sa jade. Nigba t'ayé ba ń yọ, T'o ń gbe 'Yin Rẹ ga, Awọn ogun Angel, A ma f'ayọ gbe. Njẹ, ẹ gbohun yin ga, Ki iro naa dun! Kikan lohun gooro, Yin Ọd'aguntan. AMIN

Hymn 305 – OGO ni fun Jesu | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia