Hymn 304 – E JE k'a to Jesu wa lo | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "E JE k'a to Jesu wa lo" (C&S Hymn #304, Yoruba). Ẹ JẸ k'a tọ Jesu wa lọ, Ni agbala nla ni; Nibi ti O n lọ gbadura,…
Ẹ JẸ k'a tọ Jesu wa lọ, Ni agbala nla ni; Nibi ti O n lọ gbadura, Nibi t'O n lọ kanu. K'a wo b'O ti dojubolẹ T'o n mi imi ẹdun; Ẹru ẹsẹ wa l'O gberu, Ẹsẹ gbogbo ayé. Ẹlẹsẹ, wo Oluwa rẹ, Ẹni mimọ julọ; Nitori rẹ ni Baba ko, Ayé si d'ọta rẹ. Iwọ o ha wo laironu, Lai k'ẹsẹ rẹ silẹ? Ọjọ idariji n kọja, Ọjọ igbala n lọ. AMIN
Hymn 304 – E JE k'a to Jesu wa lo | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia