Hymn 301 – IFE lo to bayi | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "IFE lo to bayi" (C&S Hymn #301, Yoruba). IFẸ lo to bayi! Ohun gbogbo pari, O ti pari gbogbo isẹ, T'o tori rẹ w'ayé.…

Hymn 301 – IFE lo to bayi | C&S Yoruba Hymnary
IFẸ lo to bayi! Ohun gbogbo pari, O ti pari gbogbo isẹ, T'o tori rẹ w'ayé. Ohun ti Baba fẹ, Ni Jesu ti se tan: Wahala ati iya Rẹ, Mu Iwe Mimọ sẹ. Ko s'irora wa kan, Ti Jesu ko jẹ ri; Gbogbo ẹdun at'aniyan, L'ọkan Rẹ si ti mọ. L'ori t'a f'ẹgun de, At'ọkan Rẹ mimọ, L'a ko gbogbo ẹsẹ wa le, K'O ba le wo wa san. Ifẹ lo mu k'O ku, Fun emi otosi; 'Wọ Etutu f'ẹsẹ gbogbo, Mo f'igbagbọ rọ mọ. Nigba aini gbogbo, Ati n'itẹ 'dajọ, Jesu, ododo Rẹ nikan, Ni igbẹkẹle mi. Jọ sisẹ ninu mi, Bi O ti se fun mi, Si jẹ ki ifẹ mi si Ọ, Ma fi ore Rẹ han. AMIN

Hymn 301 – IFE lo to bayi | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia